Native Bible

Colossians 4:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín kí ó dàpọ̀ mọ́ oore-ọ̀fẹ́ nígbà gbogbo, èyí tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ̀yin kí ó le mọ́ bí ẹ̀yin ó tí máa dá olúkúlùkù ènìyàn lóhùn.

Colossians 4:6 in English

Colossians 4:6 · Berean Standard Bible

Let your speech always be gracious, seasoned with salt, so that you may know how to answer everyone.

Context

4Ẹ gbàdúrà pé kí èmi le è máa kéde rẹ̀ kedere gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ fún mi. 5Ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ti bí ẹ ti ń ṣe pẹ̀lú àwọn tí ń bẹ lóde, kí ẹ sì máa ṣe ṣí àǹfààní tí ẹ bá nílò. 6Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín kí ó dàpọ̀ mọ́ oore-ọ̀fẹ́ nígbà gbogbo, èyí tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ̀yin kí ó le mọ́ bí ẹ̀yin ó tí máa dá olúkúlùkù ènìyàn lóhùn. 7Gbogbo bí nǹkan ti rí fún mi ní Tikiku yóò jẹ́ kí ẹ mọ̀. Òun jẹ́ arákùnrin olùfẹ́ àti olóòtítọ́ ìránṣẹ́ àti ẹlẹgbẹ́ nínú Olúwa, 8ẹni tí èmí ń rán sí yín nítorí èyí kan náà, kí ẹ̀yin lè mọ́ bí a ti wà, kí òun kí ó lè tu ọkàn yín nínú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.