Native Bible

Colossians 3:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lórí àwọn wọ̀nyí ni ìbínú Ọlọ́run ń bọ̀ wá.

Colossians 3:6 in English

Colossians 3:6 · Berean Standard Bible

Because of these, the wrath of God is coming on the sons of disobedience.*

Context

4Nígbà tí Kristi, ẹni tí í ṣe ìyè yín yóò farahàn, nígbà náà ni ẹ̀yin pẹ̀lú yóò farahàn pẹ̀lú rẹ̀ nínú ògo. 5Ẹ máa pa ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ ní ayé run: àgbèrè, panṣágà, ìwà àìmọ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti ìwọra, nítorí pé ìwọ̀nyí jásí ìbọ̀rìṣà. 6Lórí àwọn wọ̀nyí ni ìbínú Ọlọ́run ń bọ̀ wá. 7Ẹ máa ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí tẹ́lẹ̀ nígbà tí ìgbé ayé yín sì jẹ́ apá kan ayé yìí. 8Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ gbọdọ̀ fi àwọn wọ̀nyí sílẹ̀: ìbínú, ìrunú, àrankàn, fífi ọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-ba-tẹni-jẹ́ àti ọ̀rọ̀ èérí kúrò ní ètè yín.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.