Native Bible

Colossians 3:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá ń ṣe, ẹ máa fi tọkàntọkàn ṣe é fún Olúwa, kí í ṣe fún ènìyàn;

Colossians 3:23 in English

Colossians 3:23 · Berean Standard Bible

Whatever you do, work at it with your whole being, for the Lord and not for men,

Context

21Ẹ̀yin baba, ẹ má ṣe mú àwọn ọmọ yín bínú, kí wọn má bà á rẹ̀wẹ̀sì. 22Ẹ̀yin ẹrú, ẹ gbọ́ ti àwọn olówó yín nípa ti ara ní ohun gbogbo; kì í ṣe ní àrọ́júṣe, bí àwọn aláṣehàn ènìyàn; ṣùgbọ́n ní òtítọ́ inú, ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run. 23Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá ń ṣe, ẹ máa fi tọkàntọkàn ṣe é fún Olúwa, kí í ṣe fún ènìyàn; 24kí ẹ mọ̀ pé lọ́wọ́ Olúwa ni ẹ̀yin ó gba èrè, nítorí ẹ̀yin ń sìn Olúwa Kristi. 25Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe àìṣòdodo, yóò gbà á padà nítorí àìṣòdodo náà tí ó ti ṣe: kò sì ṣí ojúsàájú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.