Native Bible

Colossians 3:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ̀yin ẹrú, ẹ gbọ́ ti àwọn olówó yín nípa ti ara ní ohun gbogbo; kì í ṣe ní àrọ́júṣe, bí àwọn aláṣehàn ènìyàn; ṣùgbọ́n ní òtítọ́ inú, ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run.

Colossians 3:22 in English

Colossians 3:22 · Berean Standard Bible

Slaves, obey your earthly masters in everything, not only to please them while they are watching, but with sincerity of heart and fear of the Lord.

Context

20Ẹ̀yin ọmọ ẹ máa gbọ́ ti àwọn òbí yín ní ohun gbogbo, nítorí èyí dára gidigidi nínú Olúwa. 21Ẹ̀yin baba, ẹ má ṣe mú àwọn ọmọ yín bínú, kí wọn má bà á rẹ̀wẹ̀sì. 22Ẹ̀yin ẹrú, ẹ gbọ́ ti àwọn olówó yín nípa ti ara ní ohun gbogbo; kì í ṣe ní àrọ́júṣe, bí àwọn aláṣehàn ènìyàn; ṣùgbọ́n ní òtítọ́ inú, ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run. 23Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá ń ṣe, ẹ máa fi tọkàntọkàn ṣe é fún Olúwa, kí í ṣe fún ènìyàn; 24kí ẹ mọ̀ pé lọ́wọ́ Olúwa ni ẹ̀yin ó gba èrè, nítorí ẹ̀yin ń sìn Olúwa Kristi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.