Kolose 1:4
Colossians 1:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí a ti gbúròó ìgbàgbọ́ yín nínú Jesu Kristi, àti bí ẹ ti ṣe fẹ́ràn gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́.
Colossians 1:4 in English
Colossians 1:4 · Berean Standard Bible
because we have heard about your faith in Christ Jesus and your love for all the saints—
Context
2Sí àwọn ẹni mímọ́ àti àwọn arákùnrin àti arábìnrin nínú Kristi tí wọ́n ń gbé ní ìlú Kolose:
Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún un yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa. 3Nígbàkígbà tí a bá ń gbàdúrà fún un yín ni a máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run Baba Olúwa wa Jesu Kristi. 4Nítorí a ti gbúròó ìgbàgbọ́ yín nínú Jesu Kristi, àti bí ẹ ti ṣe fẹ́ràn gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́. 5Ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ tí ń sàn nínú ìrètí tí a gbé pamọ́ fún un yín ní ọ̀run èyí tí ẹ̀yin sì ti gbọ́ tẹ́lẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ òtítọ́ ìyìnrere náà, 6èyí tí ó ti dé ọ̀dọ̀ yín. Káàkiri àgbáyé ni ìyìnrere yìí ń so èso tí ó sì ń dàgbà, gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣe láàrín yín láti ọjọ́ náà tí ẹ ti gbọ́ ọ, tí ẹ sì ní ìmọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run nínú gbogbo òtítọ́ rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.