Amosi 4:6
Amos 4:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Èmi fún un yín ní mímọ́ eyín ní gbogbo ìlú yín, àti àìní oúnjẹ ní gbogbo ibùgbé yín, síbẹ̀, ẹ̀yin kò yípadà sọ́dọ̀ mi,” ni Olúwa wí.
Amos 4:6 in English
Amos 4:6 · Berean Standard Bible
“I beset all your cities with cleanness of teeth * and all your towns with lack of bread, yet you did not return to Me,” declares the LORD.
Context
4“Ẹ lọ sí Beteli láti dẹ́ṣẹ̀;
ẹ lọ sí Gilgali kí ẹ sì dẹ́ṣẹ̀ sí i.
Ẹ mú ẹbọ sísun yín láràárọ̀ wá,
ìdámẹ́wàá yín ní ọdọọdún mẹ́ta. 5Kí ẹ mú ọ̀rẹ́ ìdúpẹ́ ìyẹ̀fun ìwúkàrà ti a sun
kí ẹ sì mú ọrẹ àtinúwá
lọ fi wọ́n yangàn, ẹ̀yin ènìyàn Israẹli,
nítorí èyí ni ẹ fẹ́ láti ṣe,”
ni Olúwa Olódùmarè wí. 6“Èmi fún un yín ní mímọ́ eyín ní gbogbo ìlú yín,
àti àìní oúnjẹ ní gbogbo ibùgbé yín,
síbẹ̀, ẹ̀yin kò yípadà sọ́dọ̀ mi,”
ni Olúwa wí. 7“Àti pẹ̀lú mo mú òjò dúró
nígbà tí ìkórè ku oṣù mẹ́ta.
Mo rán òjò sí ibùgbé kan
ṣùgbọ́n kò rọ̀ sí ìlú mìíràn.
Oko kan ní òjò;
àwọn mìíràn kò ní ó sì gbẹ. 8Àwọn ènìyàn ń rìn láti ìlú kan sí ìlú mìíràn fún omi
wọn kò rí mu tẹ́ wọn lọ́rùn,
síbẹ̀ ẹ̀yin kò padà sí ọ̀dọ̀ mi,”
ni Olúwa wí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.