Native Bible

Amos 3:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ǹjẹ́ ẹyẹ ṣubú sínú okùn ọdẹ lórí ilẹ̀ nígbà tí a kò dẹ okùn ọdẹ fún un? Okùn ọdẹ ha lè hù jáde lórí ilẹ̀ nígbà tí kò sí ohun tí yóò mú?

Amos 3:5 in English

Amos 3:5 · Berean Standard Bible

Does a bird land in a snare where no bait has been set? Does a trap spring from the ground when it has nothing to catch?

Context

3Ẹni méjì ha à le rìn pọ̀ láìjẹ́ pé wọ́n ti pinnu láti ṣe bẹ? 4Ǹjẹ́ Kìnnìún yóò ha bú ramúramù nínú igbó, bí kò bá ní ohun ọdẹ? Ọmọ kìnnìún yóò ha ké jáde nínú ìhó rẹ̀ bí kò bá rí ohun kan mú? 5Ǹjẹ́ ẹyẹ ṣubú sínú okùn ọdẹ lórí ilẹ̀ nígbà tí a kò dẹ okùn ọdẹ fún un? Okùn ọdẹ ha lè hù jáde lórí ilẹ̀ nígbà tí kò sí ohun tí yóò mú? 6Nígbà tí ìpè bá dún ní ìlú, àwọn ènìyàn kò ha bẹ̀rù? Tí ewu bá wa lórí ìlú kò ha ṣe Olúwa ni ó fà á? 7Nítòótọ́ Olúwa Olódùmarè kò ṣe ohun kan láìfi èrò rẹ̀ hàn fun àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.