Amosi 2:1
Amos 2:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èyí ni ohun tí Olúwa wí, “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Moabu, àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà, nítorí ó ti sun ún, di eérú, egungun ọba Edomu,
Amos 2:1 in English
Amos 2:1 · Berean Standard Bible
This is what the LORD says: “For three transgressions of Moab, even four, I will not revoke My judgment,* because he burned to lime the bones of Edom’s king.
Context
1Èyí ni ohun tí Olúwa wí,
“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Moabu,
àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà,
nítorí ó ti sun ún, di eérú,
egungun ọba Edomu, 2Èmi yóò rán iná sí orí Moabu
èyí tí yóò jó àwọn ààfin Kerioti run.
Moabu yóò sì kú pẹ̀lú ariwo
pẹ̀lú igbe àti pẹ̀lú ìró ìpè. 3Èmi yóò ké onídàájọ́ rẹ̀ kúrò,
Èmi yóò sì pa gbogbo àwọn ọmọ-aládé rẹ́ nínú rẹ̀,”
ni Olúwa wí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.