Amosi 1:8
Amos 1:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi yóò ké àwọn olùgbé Aṣdodu kúrò, ti ẹni tí ó di ọ̀pá aládé ní Aṣkeloni mú. Èmi yóò yí ọwọ́ mi sí Ekroni títí tí ìyókù Filistini yóò fi ṣègbé,” ni Olúwa Olódùmarè wí.
Amos 1:8 in English
Amos 1:8 · Berean Standard Bible
I will cut off the ruler of Ashdod and the one who wields the scepter in Ashkelon. I will turn My hand against Ekron, and the remnant of the Philistines will perish,” says the Lord GOD.
Context
6Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta Gasa,
àní nítorí mẹ́rin,
Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà.
Gẹ́gẹ́ bí í oníṣòwò ẹrú,
ó kó gbogbo àwọn ènìyàn mi ní ìgbèkùn.
Ó sì tà wọ́n fún Edomu, 7Èmi yóò rán iná sí ara odi Gasa
tí yóò jó gbogbo ààfin rẹ̀ run. 8Èmi yóò ké àwọn olùgbé Aṣdodu kúrò,
ti ẹni tí ó di ọ̀pá aládé ní Aṣkeloni mú.
Èmi yóò yí ọwọ́ mi sí Ekroni
títí tí ìyókù Filistini yóò fi ṣègbé,”
ni Olúwa Olódùmarè wí. 9Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Tire
àní nítorí mẹ́rin, Èmi kì yóò yí ìpinnu ìjìyà mi padà.
Nítorí wọ́n ta gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní ìgbèkùn fún Edomu.
Wọn kò sì náání májẹ̀mú ọbàkan, 10Èmi yóò rán iná sí ara odi Tire,
tí yóò jó gbogbo àwọn ààfin rẹ̀ run.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.