Ìṣe àwọn Aposteli 9:19
Acts 9:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí ó sì jẹun, ara rẹ̀ mókun.
Acts 9:19 in English
Acts 9:19 · Berean Standard Bible
and after taking some food, he regained his strength. And he spent several days with the disciples in Damascus.
Context
17Anania sì lọ, ó sì wọ ilé náà, nígbà tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé Saulu, ó sì wí pé, “Arákùnrin Saulu, Olúwa ni ó rán mi, Jesu tí ó fi ara hàn ọ lọ́nà tí ìwọ bá wá, kí ìwọ ba à lè ríran, kí ó sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́.” 18Lójúkan náà nǹkan kan ti ó dàbí ìpẹ́ sì bọ kúrò lójú rẹ̀, ó sì ríran; ó sì dìde, a sì bamitiisi rẹ̀. 19Nígbà tí ó sì jẹun, ara rẹ̀ mókun. 20(19) Saulu sì wá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ní Damasku ní ọjọ́ púpọ̀. (20) Lójúkan náà ó sì ń wàásù Kristi nínú àwọn Sinagọgu pé, Jesu ni Ọmọ Ọlọ́run. 21Ẹnu sì yà gbogbo àwọn ti ó ń gbọ́, wọn sì wí pé, “Èyí ha kọ ẹni ti ó ti fóòro àwọn ti ń pe orúkọ yìí ni Jerusalẹmu? Nítorí èyí náà ni ó sa ṣe wá sí ìhín yìí, láti mú wọn ní dìde lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.