Native Bible

Acts 7:46 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹni tí ó rí ojúrere níwájú Ọlọ́run, tí ó sì tọrọ láti rí ibùgbé fún Ọlọ́run Jakọbu.

Acts 7:46 in English

Acts 7:46 · Berean Standard Bible

who found favor in the sight of God and asked to provide a dwelling place for the God of Jacob.*

Context

44“Àwọn baba wa ní àgọ́ ẹ̀rí pẹ̀lú wọn ní ijù. Èyí tí a ṣe gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tí ó ba Mose sọ̀rọ̀ pé kí ó ṣe é, gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tí ó ti rí. 45Ti àwọn baba wa tí ó tẹ̀lé wọn sí mú bá Joṣua wá sí ilẹ̀ ìní àwọn aláìkọlà, tí Ọlọ́run lè jáde kúrò níwájú àwọn baba wa, títí dí àkókò Dafidi. 46Ẹni tí ó rí ojúrere níwájú Ọlọ́run, tí ó sì tọrọ láti rí ibùgbé fún Ọlọ́run Jakọbu. 47Ṣùgbọ́n Solomoni ni ó kọ́ ilé fún un. 48“Ṣùgbọ́n Ọ̀gá-ògo kì í gbé ilé ti a fi ọwọ́ kọ́, gẹ́gẹ́ bí wòlíì ti wí pé:

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.