Ìṣe àwọn Aposteli 5:6
Acts 5:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sí dìde, wọ́n dì í, wọn sì gbé è jáde, wọn sì sin ín.
Acts 5:6 in English
Acts 5:6 · Berean Standard Bible
Then the young men stepped forward, wrapped up his body, and carried him out and buried him.
Context
4Nígbà tí ó wà níbẹ̀ tìrẹ kọ́ ní í ṣe? Nígbà tí a sì ta á tan, kò ha wà ní ìkáwọ́ rẹ̀? Èéha ti ṣe tí ìwọ fi rò nǹkan yìí lọ́kàn rẹ? Ènìyàn kọ́ ni ìwọ ṣèké sí bí kò ṣe sí Ọlọ́run?” 5Nígbà tí Anania sí gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó ṣubú lulẹ̀, ó sì kú, ẹ̀rù ńlá sí ba gbogbo àwọn tí ó gbọ́. 6Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sí dìde, wọ́n dì í, wọn sì gbé è jáde, wọn sì sin ín. 7Ó sì tó bí ìwọ̀n wákàtí mẹ́ta, aya rẹ̀ láìmọ̀ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀, ó wọlé. 8Peteru sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Wí fún mi, ṣé iye yìí ni ìwọ àti Anania gbà lórí ilẹ̀?”
Ó sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, iye rẹ̀ náà ni.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.