Native Bible

Acts 5:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n ní òru, angẹli Olúwa ṣí ìlẹ̀kùn túbú; ó sì mú wọn jáde.

Acts 5:19 in English

Acts 5:19 · Berean Standard Bible

But during the night an angel of the Lord opened the doors of the jail and brought them out, saying,

Context

17Nígbà náà ni ẹ̀mí owú gbígbóná gbé olórí àlùfáà àti gbogbo àwọn tí wọn wà lọ́dọ̀ rẹ̀ tí ì ṣe ẹ̀yà tí àwọn Sadusi wọ̀. 18Wọ́n sì nawọ́ mú àwọn aposteli wọn sì fi wọ́n sínú túbú. 19Ṣùgbọ́n ní òru, angẹli Olúwa ṣí ìlẹ̀kùn túbú; ó sì mú wọn jáde. 20Ó sì wí pé “Ẹ lọ dúró nínú tẹmpili kí ẹ sì máa ṣọ́ ọ̀rọ̀ ìyè yìí ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ fún àwọn ènìyàn.” 21Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ èyí, wọ́n wọ tẹmpili lọ ní kùtùkùtù, wọ́n sì ń kọ́ni. Nígbà tí olórí àlùfáà àti àwọn ti ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ dé, wọn sì pè àpéjọ ìgbìmọ̀, àti gbogbo àwọn àgbàgbà àwọn ọmọ Israẹli, wọn sì ránṣẹ́ sí ilé túbú láti mú àwọn aposteli wá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.