Ìṣe àwọn Aposteli 5:14
Acts 5:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n síbẹ̀síbẹ̀, a sì ń yan àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin tí ó gba Olúwa gbọ́ kún iye wọn sí i.
Acts 5:14 in English
Acts 5:14 · Berean Standard Bible
Yet more and more believers were brought to the Lord—large numbers of both men and women.
Context
12A sì ti ọwọ́ àwọn aposteli ṣe iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu púpọ̀ láàrín àwọn ènìyàn. Gbogbo wọn sì fi ọkàn kan wà ní ìloro Solomoni. 13Kò sí nínú àwọn ìyókù tí ó jẹ́ gbìyànjú láti darapọ̀ mọ́ wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ń fi ọ̀wọ̀ gíga fún wọn. 14Ṣùgbọ́n síbẹ̀síbẹ̀, a sì ń yan àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin tí ó gba Olúwa gbọ́ kún iye wọn sí i. 15Tó bẹ́ẹ̀ tí wọn ń gbé àwọn abirùn jáde sí òpópónà, tí wọn ń tẹ́ wọn sí orí ibùsùn àti àkéte kí òjìji Peteru ba à le gba orí ẹlòmíràn nínú wọn bí ó bá ti ń kọjá lọ. 16Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì kó ara wọn jọ láti àwọn ìlú tí ó yí Jerusalẹmu ká, wọn ń mú àwọn abirùn wá àti àwọn tí ara kan fún ẹ̀mí àìmọ́; a sì mu olúkúlùkù wọn ní ara dá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.