Ìṣe àwọn Aposteli 4:3
Acts 4:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọn sì nawọ́ mú wọn, wọn sì tì wọ́n mọ́ ilé túbú títí ó fi dí ọjọ́ kejì; nítorí tí alẹ́ ti lẹ́ tan.
Acts 4:3 in English
Acts 4:3 · Berean Standard Bible
They seized Peter and John, and because it was evening, they put them in custody until the next day.
Context
1Bí wọn sì tí ń bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀, àwọn àlùfáà àti olórí ẹ̀ṣọ́ tẹmpili àti àwọn Sadusi dìde sí wọn. 2Inú bí wọn, nítorí tí wọn kọ́ àwọn ènìyàn, wọ́n sì ń wàásù àjíǹde kúrò nínú òkú nínú Jesu. 3Wọn sì nawọ́ mú wọn, wọn sì tì wọ́n mọ́ ilé túbú títí ó fi dí ọjọ́ kejì; nítorí tí alẹ́ ti lẹ́ tan. 4Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà gbàgbọ́; iye àwọn ọkùnrin náà sì tó ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000). 5Ó sì ṣe ní ọjọ́ kejì, àwọn olórí wọn àti àwọn alàgbà àti àwọn olùkọ́ni ní òfin péjọ sí Jerusalẹmu.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.