Native Bible

Acts 28:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí èyí sì ṣetán, àwọn ìyókù tí ó ni ààrùn ni erékùṣù náà tọ̀ ọ́ wá, ó sì mú wọn láradá.

Acts 28:9 in English

Acts 28:9 · Berean Standard Bible

After this had happened, the rest of the sick on the island came and were cured as well.

Context

7Ní agbègbè ibẹ̀ ni ilé ọkùnrin ọlọ́lá erékùṣù náà wà, orúkọ ẹni tí a ń pè ní Pubiliu; ẹni tí ó ti ipa inú rere gbà wá sí ọ̀dọ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta. 8Ó sì ṣe, baba Pubiliu dùbúlẹ̀ àìsàn ibà àti ìgbẹ́-ọ̀rìn; ẹni tí Paulu wọlé tọ̀ lọ, tí ó sì gbàdúrà fún, nígbà tí ó sì fi ọwọ́ lé e, ó sì mú un láradá. 9Nígbà tí èyí sì ṣetán, àwọn ìyókù tí ó ni ààrùn ni erékùṣù náà tọ̀ ọ́ wá, ó sì mú wọn láradá. 10Wọ́n sì bu ọlá púpọ̀ fún wa; nígbà tí a ń lọ, wọ́n sì fún wa ní ohun púpọ̀ tí a nílò ní ọ̀nà àjò wa. 11Lẹ́yìn oṣù mẹ́ta, a wọ ọkọ̀ ojú omi kan èyí tí ó lo àkókò òtútù ní erékùṣù náà. Ó jẹ́ ọkọ̀ ojú omi ti Alekisandiria, èyí tí àmì rẹ̀ jẹ́ tí òrìṣà ìbejì ti Kasitoru òun Polukisu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.