Ìṣe àwọn Aposteli 28:8
Acts 28:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì ṣe, baba Pubiliu dùbúlẹ̀ àìsàn ibà àti ìgbẹ́-ọ̀rìn; ẹni tí Paulu wọlé tọ̀ lọ, tí ó sì gbàdúrà fún, nígbà tí ó sì fi ọwọ́ lé e, ó sì mú un láradá.
Acts 28:8 in English
Acts 28:8 · Berean Standard Bible
The father of Publius was sick in bed, suffering from fever and dysentery. Paul went in to see him, and after praying and placing his hands on him, he healed the man.
Context
6Ṣùgbọ́n wọn ń wòye ìgbà tí yóò wù, tàbí tí yóò sì ṣubú lulẹ̀ láti kú lójijì; nígbà tí wọ́n wò títí, tí wọn kò sì rí nǹkan kan kí ó ṣe é, wọ́n pa èrò wọn dà pé, òrìṣà kan ni ọkùnrin yìí. 7Ní agbègbè ibẹ̀ ni ilé ọkùnrin ọlọ́lá erékùṣù náà wà, orúkọ ẹni tí a ń pè ní Pubiliu; ẹni tí ó ti ipa inú rere gbà wá sí ọ̀dọ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta. 8Ó sì ṣe, baba Pubiliu dùbúlẹ̀ àìsàn ibà àti ìgbẹ́-ọ̀rìn; ẹni tí Paulu wọlé tọ̀ lọ, tí ó sì gbàdúrà fún, nígbà tí ó sì fi ọwọ́ lé e, ó sì mú un láradá. 9Nígbà tí èyí sì ṣetán, àwọn ìyókù tí ó ni ààrùn ni erékùṣù náà tọ̀ ọ́ wá, ó sì mú wọn láradá. 10Wọ́n sì bu ọlá púpọ̀ fún wa; nígbà tí a ń lọ, wọ́n sì fún wa ní ohun púpọ̀ tí a nílò ní ọ̀nà àjò wa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.