Native Bible

Acts 28:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn arákùnrin ibẹ̀ gbúròó pé a ń bọ̀, wọ́n sì rìnrìn àjò títí wọ́n fi dé Apii Foroni àti sí ilé èrò mẹ́ta láti pàdé wa: nígbà tí Paulu sì rí wọn, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì mú ọkàn le.

Acts 28:15 in English

Acts 28:15 · Berean Standard Bible

The brothers there had heard about us and traveled as far as the Forum of Appius * and the Three Taverns * to meet us. When Paul saw them, he was encouraged and gave thanks to God.

Context

13Láti ibẹ̀ nígbà tí a lọ yíká; a dé Regiomu: nígbà tí ó sì di ọjọ́ kejì, afẹ́fẹ́ gúúsù bẹ̀rẹ̀ sí ní fẹ́, ní ọjọ́ kejì rẹ̀ a sì dé Puteoli. 14A sì rí àwọn arákùnrin kan níbẹ̀, tí wọ́n sì bẹ̀ wá láti bá wọn gbé fún ọjọ́ méje: bẹ́ẹ̀ ni a sì lọ sí ìhà Romu. 15Àwọn arákùnrin ibẹ̀ gbúròó pé a ń bọ̀, wọ́n sì rìnrìn àjò títí wọ́n fi dé Apii Foroni àti sí ilé èrò mẹ́ta láti pàdé wa: nígbà tí Paulu sì rí wọn, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì mú ọkàn le. 16Nígbà tí a sì dé Romu, olórí àwọn ọmọ-ogun fi àwọn òǹdè lé olórí ẹ̀ṣọ́ lọ́wọ́, ṣùgbọ́n wọ́n gba Paulu láààyè láti máa dágbé fún ara rẹ̀ pẹ̀lú ọmọ-ogun tí ó ń ṣọ́ ọ. 17Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, Paulu pe àwọn olórí Júù jọ. Nígbà tí wọ́n sì péjọ, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ara, bí ó ti ṣe pé èmi kò ṣe ohun kan lòdì sí àwọn ènìyàn, tàbí sí àṣà àwọn baba wa, síbẹ̀ wọ́n fi mí lé àwọn ara Romu lọ́wọ́ ní òǹdè láti Jerusalẹmu wá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.