Native Bible

Acts 28:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

A sì rí àwọn arákùnrin kan níbẹ̀, tí wọ́n sì bẹ̀ wá láti bá wọn gbé fún ọjọ́ méje: bẹ́ẹ̀ ni a sì lọ sí ìhà Romu.

Acts 28:14 in English

Acts 28:14 · Berean Standard Bible

There we found some brothers who invited us to spend the week with them. And so we came to Rome.

Context

12Nígbà tí a sì gúnlẹ̀ ní Sirakusi, a gbé ibẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta. 13Láti ibẹ̀ nígbà tí a lọ yíká; a dé Regiomu: nígbà tí ó sì di ọjọ́ kejì, afẹ́fẹ́ gúúsù bẹ̀rẹ̀ sí ní fẹ́, ní ọjọ́ kejì rẹ̀ a sì dé Puteoli. 14A sì rí àwọn arákùnrin kan níbẹ̀, tí wọ́n sì bẹ̀ wá láti bá wọn gbé fún ọjọ́ méje: bẹ́ẹ̀ ni a sì lọ sí ìhà Romu. 15Àwọn arákùnrin ibẹ̀ gbúròó pé a ń bọ̀, wọ́n sì rìnrìn àjò títí wọ́n fi dé Apii Foroni àti sí ilé èrò mẹ́ta láti pàdé wa: nígbà tí Paulu sì rí wọn, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì mú ọkàn le. 16Nígbà tí a sì dé Romu, olórí àwọn ọmọ-ogun fi àwọn òǹdè lé olórí ẹ̀ṣọ́ lọ́wọ́, ṣùgbọ́n wọ́n gba Paulu láààyè láti máa dágbé fún ara rẹ̀ pẹ̀lú ọmọ-ogun tí ó ń ṣọ́ ọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.