Native Bible

Acts 27:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn atukọ̀ ń wá ọ̀nà láti sá kúrò nínú ọkọ̀, tí wọ́n sì ti sọ àwọn ọkọ̀ kéékèèké kalẹ̀ sí ojú Òkun, bí ẹni pé wọn ń fẹ́ sọ ìdákọ̀ró sílẹ̀ níwájú ọkọ̀.

Acts 27:30 in English

Acts 27:30 · Berean Standard Bible

Meanwhile, the sailors attempted to escape from the ship. Pretending to lower anchors from the bow, they let the lifeboat down into the sea.

Context

28Nígbà tí wọ́n sì wọn Òkun, wọ́n rí i ó jì ní ogún ìgbọ̀nwọ́, nígbà tì í wọ́n sún síwájú díẹ̀, wọ́n sì tún wọn Òkun, wọn rí i pé ó jì ni ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. 29Nígbà tí wọ́n bẹ̀rù kí wọn má ṣe rọ́ lu orí òkúta, wọ́n sọ ìdákọ̀ró mẹ́rin sílẹ̀ ni ìdí ọkọ̀, wọ́n ń retí ojúmọ́. 30Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn atukọ̀ ń wá ọ̀nà láti sá kúrò nínú ọkọ̀, tí wọ́n sì ti sọ àwọn ọkọ̀ kéékèèké kalẹ̀ sí ojú Òkun, bí ẹni pé wọn ń fẹ́ sọ ìdákọ̀ró sílẹ̀ níwájú ọkọ̀. 31Paulu wí fún balógun ọ̀rún àti fún àwọn ọmọ-ogun pé, “Bí kò ṣe pé àwọn wọ̀nyí bá dúró nínú ọkọ̀ ẹ̀yin kí yóò lè là!” 32Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ogun gé okùn àwọn ọkọ̀ kéékèèké, wọ́n jù ú sílẹ̀ kí ó ṣubú sọ́hùn-ún.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.