Ìṣe àwọn Aposteli 22:4
Acts 22:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mo sì ṣe inúnibíni sí àwọn ènìyàn tí ń tọ ọ̀nà yìí dé ojú ikú wọn, mo dè tọkùnrin tobìnrin wọ́n, mo sì fi wọ́n sínú túbú,
Acts 22:4 in English
Acts 22:4 · Berean Standard Bible
I persecuted this Way even to the death, detaining both men and women and throwing them into prison,
Context
2Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ pé ó ń bá wọn sọ̀rọ̀ ni èdè Aramaiki, wọ́n túbọ̀ dákẹ́ jẹ́ẹ́.
Nígbà náà ni ó wí pé, 3“Júù ni èmi í ṣe, a bí mi ni Tarsu ìlú kan ní Kilikia, ṣùgbọ́n tí a tọ́ mi dàgbà ni ìlú yìí. Ní abẹ́ ẹsẹ̀ Gamalieli ni a sì gbé kọ́ mi ní òfin àwọn baba wa, tí mo sì ní ìtara fún Ọlọ́run àní gẹ́gẹ́ bí gbogbo yin tí rí ni òní. 4Mo sì ṣe inúnibíni sí àwọn ènìyàn tí ń tọ ọ̀nà yìí dé ojú ikú wọn, mo dè tọkùnrin tobìnrin wọ́n, mo sì fi wọ́n sínú túbú, 5àní bí olórí àlùfáà pẹ̀lú gbogbo àjọ àwọn alàgbà tí lè jẹ́ mi ní ẹ̀rí. Mo tilẹ̀ gba ìwé àṣẹ lọ́wọ́ wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin wọn ní Damasku láti mú àwọn tí ó wà níbẹ̀ ní dídè wá sí Jerusalẹmu, láti jẹ wọ́n ní yà. 6“Bí èmi tí súnmọ́ etí Damasku níwọ̀n ọjọ́-kanrí, lójijì ìmọ́lẹ̀ ńlá láti ọ̀run wá mọ́lẹ̀ yí mi ká.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.