Ìṣe àwọn Aposteli 22:2
Acts 22:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ pé ó ń bá wọn sọ̀rọ̀ ni èdè Aramaiki, wọ́n túbọ̀ dákẹ́ jẹ́ẹ́. Nígbà náà ni ó wí pé,
Acts 22:2 in English
Acts 22:2 · Berean Standard Bible
When they heard him speak to them in Hebrew,* they became even more silent. Then Paul declared,
Context
1“Ẹ̀yin ará àti baba, ẹ gbọ́ tí ẹnu mi nísinsin yìí.” 2Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ pé ó ń bá wọn sọ̀rọ̀ ni èdè Aramaiki, wọ́n túbọ̀ dákẹ́ jẹ́ẹ́.
Nígbà náà ni ó wí pé, 3“Júù ni èmi í ṣe, a bí mi ni Tarsu ìlú kan ní Kilikia, ṣùgbọ́n tí a tọ́ mi dàgbà ni ìlú yìí. Ní abẹ́ ẹsẹ̀ Gamalieli ni a sì gbé kọ́ mi ní òfin àwọn baba wa, tí mo sì ní ìtara fún Ọlọ́run àní gẹ́gẹ́ bí gbogbo yin tí rí ni òní. 4Mo sì ṣe inúnibíni sí àwọn ènìyàn tí ń tọ ọ̀nà yìí dé ojú ikú wọn, mo dè tọkùnrin tobìnrin wọ́n, mo sì fi wọ́n sínú túbú,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.