Ìṣe àwọn Aposteli 22:25
Acts 22:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí wọ́n sí tí fi ọṣán dè é, Paulu bí balógun ọ̀rún tí ó dúró tì í pé, “Ó ha tọ́ fún yín láti na ẹni tí i ṣe ará Romu ni àìdálẹ́bi bí?”
Acts 22:25 in English
Acts 22:25 · Berean Standard Bible
But as they stretched him out to strap him down, Paul said to the centurion standing there, “Is it lawful for you to flog a Roman citizen without a trial?”
Context
23Bí wọ́n sì ti ń kígbe, tí wọ́n sì ń jú aṣọ wọn káàkiri, tí wọ́n ń ku eruku sí ojú ọ̀run, 24olórí ogun pàṣẹ pé kí a mú Paulu wá sínú àgọ́ àwọn ológun. Ó sì pàṣẹ kí wọ́n ó lù ú, kí wọn fi ọ̀rọ̀ wa lẹ́nu wò, kí òun ba à lè mọ ìdí tí wọ́n fi ń kígbe lé e lórí bẹ́ẹ̀. 25Bí wọ́n sí tí fi ọṣán dè é, Paulu bí balógun ọ̀rún tí ó dúró tì í pé, “Ó ha tọ́ fún yín láti na ẹni tí i ṣe ará Romu ni àìdálẹ́bi bí?” 26Nígbà tí balógun ọ̀rún sì gbọ́ èyí, ó lọ wí fún olórí ogun pé, “Kín ni ó fẹ́ ṣe yìí: nítorí ọkùnrin yìí ará Romu ní i ṣe?” 27Alábojútó-ogun sì dé, ó sì bí Paulu pé, “Sọ fún mi, ará Romu ni ìwọ jẹ́ bí?”
Ó sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.