Ìṣe àwọn Aposteli 22:24
Acts 22:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
olórí ogun pàṣẹ pé kí a mú Paulu wá sínú àgọ́ àwọn ológun. Ó sì pàṣẹ kí wọ́n ó lù ú, kí wọn fi ọ̀rọ̀ wa lẹ́nu wò, kí òun ba à lè mọ ìdí tí wọ́n fi ń kígbe lé e lórí bẹ́ẹ̀.
Acts 22:24 in English
Acts 22:24 · Berean Standard Bible
the commander ordered that Paul be brought into the barracks. He directed that Paul be flogged and interrogated to determine the reason for this outcry against him.
Context
22Wọ́n sì fi etí sí ọ̀rọ̀ Paulu títí tí ó fi sọ ọ̀rọ̀ yìí. Nígbà yìí ni wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì kígbe wí pé, “Ẹ mu ẹni yìí kúrò láyé! Kò yẹ kí ó wà láààyè!” 23Bí wọ́n sì ti ń kígbe, tí wọ́n sì ń jú aṣọ wọn káàkiri, tí wọ́n ń ku eruku sí ojú ọ̀run, 24olórí ogun pàṣẹ pé kí a mú Paulu wá sínú àgọ́ àwọn ológun. Ó sì pàṣẹ kí wọ́n ó lù ú, kí wọn fi ọ̀rọ̀ wa lẹ́nu wò, kí òun ba à lè mọ ìdí tí wọ́n fi ń kígbe lé e lórí bẹ́ẹ̀. 25Bí wọ́n sí tí fi ọṣán dè é, Paulu bí balógun ọ̀rún tí ó dúró tì í pé, “Ó ha tọ́ fún yín láti na ẹni tí i ṣe ará Romu ni àìdálẹ́bi bí?” 26Nígbà tí balógun ọ̀rún sì gbọ́ èyí, ó lọ wí fún olórí ogun pé, “Kín ni ó fẹ́ ṣe yìí: nítorí ọkùnrin yìí ará Romu ní i ṣe?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.