Native Bible

Acts 22:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì dúró tì mí, ó sì wí fún mi pé, ‘Arákùnrin Saulu, gba ìríran!’ Ní ẹsẹ̀ kan náà, mo sì ṣí ojú sí òkè mo sì lè rí i.

Acts 22:13 in English

Acts 22:13 · Berean Standard Bible

came and stood beside me. ‘Brother Saul,’ he said, ‘receive your sight.’ And at that moment I could see him.

Context

11Àwọn tí ó sì wà pẹ̀lú mi fà mí lọ́wọ́ wọ Damasku lọ nítorí tí èmi kò lè ríran nítorí ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ náà ti fọ́ mi ní ojú. 12“Ọkùnrin kan tí a ń pè ní Anania tọ̀ mí wá, ẹni tó jẹ́ olùfọkànsìn ti òfin, tí ó sì lórúkọ rere lọ́dọ̀ gbogbo àwọn Júù tí ó ń gbé ibẹ̀. 13Ó sì dúró tì mí, ó sì wí fún mi pé, ‘Arákùnrin Saulu, gba ìríran!’ Ní ẹsẹ̀ kan náà, mo sì ṣí ojú sí òkè mo sì lè rí i. 14“Nígbà náà ni ó wí pé: ‘Ọlọ́run àwọn baba wa ti yàn ọ́ láti mọ ìfẹ́ rẹ̀, àti láti ri Ẹni òdodo náà, àti láti gbọ́ ọ̀rọ̀ láti ẹnu rẹ̀. 15Ìwọ yóò jẹ́ ẹlẹ́rìí rẹ̀ fún gbogbo ènìyàn, nínú ohun tí ìwọ tí rí tí ìwọ sì ti gbọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.