Native Bible

Acts 22:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn tí ó sì wà pẹ̀lú mi fà mí lọ́wọ́ wọ Damasku lọ nítorí tí èmi kò lè ríran nítorí ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ náà ti fọ́ mi ní ojú.

Acts 22:11 in English

Acts 22:11 · Berean Standard Bible

Because the brilliance of the light had blinded me, my companions led me by the hand into Damascus.

Context

9Àwọn tí ó sì wà pẹ̀lú mi rí ìmọ́lẹ̀ náà nítòótọ́, ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́ ohùn ẹni tí ń bá mi sọ̀rọ̀. 10“Mo sí béèrè pé, ‘Kín ni kí èmí kí ó ṣe, Olúwa?’ “Olúwa sì wí fún mi pé, ‘Dìde, kí o sì lọ sí Damasku; níbẹ̀ ni a ó sì ti sọ ohun gbogbo fún ọ tí a yàn fún ọ láti ṣe.’ 11Àwọn tí ó sì wà pẹ̀lú mi fà mí lọ́wọ́ wọ Damasku lọ nítorí tí èmi kò lè ríran nítorí ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ náà ti fọ́ mi ní ojú. 12“Ọkùnrin kan tí a ń pè ní Anania tọ̀ mí wá, ẹni tó jẹ́ olùfọkànsìn ti òfin, tí ó sì lórúkọ rere lọ́dọ̀ gbogbo àwọn Júù tí ó ń gbé ibẹ̀. 13Ó sì dúró tì mí, ó sì wí fún mi pé, ‘Arákùnrin Saulu, gba ìríran!’ Ní ẹsẹ̀ kan náà, mo sì ṣí ojú sí òkè mo sì lè rí i.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.