Ìṣe àwọn Aposteli 21:22
Acts 21:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ǹjẹ́ èwo ni ṣíṣe? Ìjọ kò lè ṣàìmá péjọpọ̀: dájúdájú wọn yóò gbọ́ pé, ìwọ dé.
Acts 21:22 in English
Acts 21:22 · Berean Standard Bible
What then should we do? They will certainly hear that you have come.
Context
20Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, wọ́n yin Ọlọ́run lógo, wọ́n sì wí fún un pé, “Arákùnrin, ìwọ rí iye ẹgbẹẹgbẹ̀rún nínú àwọn Júù tí ó gbàgbọ́, gbogbo wọn ni ó sì ní ìtara fún òfin. 21Wọ́n sì ti ròyìn rẹ̀ fún wọn pé, ìwọ ń kọ́ gbogbo àwọn Júù tí ó wà láàrín àwọn aláìkọlà pé, kí wọn kọ Mose sílẹ̀, ó ń wí fún wọn pé kí wọn má ṣe kọ àwọn ọmọ wọn ní ilà mọ́, kí wọn má sì ṣe rìn gẹ́gẹ́ bí àṣà wọn. 22Ǹjẹ́ èwo ni ṣíṣe? Ìjọ kò lè ṣàìmá péjọpọ̀: dájúdájú wọn yóò gbọ́ pé, ìwọ dé. 23Ǹjẹ́ èyí tí àwa ó wí fún ọ yìí ni kí o ṣe, àwa ni ọkùnrin mẹ́rin tí wọ́n wà lábẹ́ ẹ̀jẹ́. 24Àwọn ni kí ìwọ mú, kí o sì ṣe ìwẹ̀nùmọ́ pẹ̀lú wọn, kí ó sì san owó láti fá irun orí wọn: gbogbo ènìyàn yóò sì mọ̀ pé, kò sì òtítọ́ kan nínú ohun tí wọ́n gbọ́ sí ọ; àti pé, ìwọ tìkára rẹ ń rìn déédé, ìwọ sì ń pa òfin Mose mọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.