Ìṣe àwọn Aposteli 20:36
Acts 20:36 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí ó sì tí wí nǹkan wọ̀nyí, ó kúnlẹ̀, ó sì bá gbogbo wọn gbàdúrà.
Acts 20:36 in English
Acts 20:36 · Berean Standard Bible
When Paul had said this, he knelt down with all of them and prayed.
Context
34Ẹ̀yin tìkára yín sá à mọ̀ pé, ọwọ́ mi wọ̀nyí ni mo fi ṣiṣẹ́ láti fi pèsè fún àìní mi, àti tí àwọn tí ó wà pẹ̀lú mi. 35Nínú ohun gbogbo mo fi àpẹẹrẹ fún un yín pé, nípa ṣíṣe iṣẹ́ bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí ẹ máa ran àwọn aláìlera lọ́wọ́, ki ẹ sì máa rántí ọ̀rọ̀ Jesu Olúwa, bí òun tìkára rẹ̀ tí wí pé, ‘Láti fún ni ní ìbùkún ju láti gbà lọ.’ ” 36Nígbà tí ó sì tí wí nǹkan wọ̀nyí, ó kúnlẹ̀, ó sì bá gbogbo wọn gbàdúrà. 37Gbogbo wọn sì sọkún gidigidi, wọ́n sì rọ̀ mọ́ Paulu lọ́rùn, wọ́n sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu. 38Inú wọn sì bàjẹ́ jùlọ fún ọ̀rọ̀ tí ó sọ pé, wọn kì yóò rí ojú òun mọ́, wọ́n sì sìn ín títí dé inú ọkọ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.