Native Bible

Acts 20:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní àti Miletu ni Paulu ti ránṣẹ́ sí Efesu, láti pé àwọn alàgbà ìjọ wá sọ́dọ̀ rẹ̀.

Acts 20:17 in English

Acts 20:17 · Berean Standard Bible

From Miletus, Paul sent to Ephesus for the elders of the church.

Context

15Nígbà tí a sì ṣíkọ̀ kúrò níbẹ̀, ní ọjọ́ kejì a dé ọ̀kánkán Kiosi; ní ọjọ́ kejì rẹ̀ a dé Samosi, ni ọjọ́ kejì rẹ̀ a sì dé Miletu. 16Paulu ṣa ti pinnu rẹ̀ láti bá ọkọ̀ ojú omi kọjá sí Efesu, nítorí ki ó má ba à lo àkókò kankan ni Asia: nítorí tí ó ń yára bí yóò ṣe ṣe é ṣe fún un láti wà ní Jerusalẹmu lọ́jọ́ Pentikosti. 17Ní àti Miletu ni Paulu ti ránṣẹ́ sí Efesu, láti pé àwọn alàgbà ìjọ wá sọ́dọ̀ rẹ̀. 18Nígbà tí wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin tìkára yín mọ̀, láti ọjọ́ kìn-ín-ní tí mo tí dé Asia, bí mo ti bá yín gbé, ní gbogbo àkókò náà. 19Bí mo ti ń fi ìrẹ̀lẹ̀ inú gbogbo sin Olúwa, àti omijé púpọ̀, pẹ̀lú ìdánwò, tí ó bá mi, nípa rìkíṣí àwọn Júù.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.