Native Bible

Acts 20:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Paulu ṣa ti pinnu rẹ̀ láti bá ọkọ̀ ojú omi kọjá sí Efesu, nítorí ki ó má ba à lo àkókò kankan ni Asia: nítorí tí ó ń yára bí yóò ṣe ṣe é ṣe fún un láti wà ní Jerusalẹmu lọ́jọ́ Pentikosti.

Acts 20:16 in English

Acts 20:16 · Berean Standard Bible

Paul had decided to sail past Ephesus to avoid spending time in the province of Asia, because he was in a hurry to reach Jerusalem, if possible, by the day of Pentecost.*

Context

14Nígbà tí ó sì pàdé wa ní Asosi, a gbà á sínú ọkọ̀, a sì wá sí Miletu. 15Nígbà tí a sì ṣíkọ̀ kúrò níbẹ̀, ní ọjọ́ kejì a dé ọ̀kánkán Kiosi; ní ọjọ́ kejì rẹ̀ a dé Samosi, ni ọjọ́ kejì rẹ̀ a sì dé Miletu. 16Paulu ṣa ti pinnu rẹ̀ láti bá ọkọ̀ ojú omi kọjá sí Efesu, nítorí ki ó má ba à lo àkókò kankan ni Asia: nítorí tí ó ń yára bí yóò ṣe ṣe é ṣe fún un láti wà ní Jerusalẹmu lọ́jọ́ Pentikosti. 17Ní àti Miletu ni Paulu ti ránṣẹ́ sí Efesu, láti pé àwọn alàgbà ìjọ wá sọ́dọ̀ rẹ̀. 18Nígbà tí wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin tìkára yín mọ̀, láti ọjọ́ kìn-ín-ní tí mo tí dé Asia, bí mo ti bá yín gbé, ní gbogbo àkókò náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.