Native Bible

Acts 20:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà ti àwa sì ṣáájú, àwa sì ṣíkọ̀ lọ sì Asosi, níbẹ̀ ni a ti lérò láti gba Paulu sínú ọkọ̀: nítorí bẹ́ẹ̀ ni ó tí pinnu rẹ̀, òun tìkára rẹ̀ ń fẹ́ bá ti ọ̀nà-ẹsẹ̀ lọ.

Acts 20:13 in English

Acts 20:13 · Berean Standard Bible

We went on ahead to the ship and sailed to Assos, where we were to take Paul aboard. He had arranged this because he was going there on foot.

Context

11Nígbà tí ó sì tún gòkè lọ, ó sì jẹ oúnjẹ Olúwa, ó sì sọ̀rọ̀ pẹ́ títí ó fi di àfẹ̀mọ́júmọ́, nígbà náà ni ó sì lọ. 12Wọ́n sì mú ọmọkùnrin náà lọ sílẹ̀ láààyè, inú gbogbo wọn sì dùn lọ́pọ̀lọ́pọ̀. 13Nígbà ti àwa sì ṣáájú, àwa sì ṣíkọ̀ lọ sì Asosi, níbẹ̀ ni a ti lérò láti gba Paulu sínú ọkọ̀: nítorí bẹ́ẹ̀ ni ó tí pinnu rẹ̀, òun tìkára rẹ̀ ń fẹ́ bá ti ọ̀nà-ẹsẹ̀ lọ. 14Nígbà tí ó sì pàdé wa ní Asosi, a gbà á sínú ọkọ̀, a sì wá sí Miletu. 15Nígbà tí a sì ṣíkọ̀ kúrò níbẹ̀, ní ọjọ́ kejì a dé ọ̀kánkán Kiosi; ní ọjọ́ kejì rẹ̀ a dé Samosi, ni ọjọ́ kejì rẹ̀ a sì dé Miletu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.