Ìṣe àwọn Aposteli 2:30
Acts 2:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n ó jẹ́ wòlíì, àti bí ó mọ́ pé, Ọlọ́run ti ṣe ìlérí fún òun nínú ìbúra pé nínú irú-ọmọ inú rẹ̀, òun yóò mú ọ̀kan jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀.
Acts 2:30 in English
Acts 2:30 · Berean Standard Bible
But he was a prophet and knew that God had promised him on oath that He would place one of his descendants on his throne.*
Context
28Ìwọ mú mi mọ ọ̀nà ìyè,
ìwọ yóò mú mi kún fún ayọ̀ ni iwájú rẹ.’ 29“Ará, èmí lè sọ fún yín pẹ̀lú ìgboyà pé Dafidi baba ńlá kú, a sì sin ín, ibojì rẹ̀ sì ń bẹ lọ́dọ̀ wa títí di òní yìí. 30Ṣùgbọ́n ó jẹ́ wòlíì, àti bí ó mọ́ pé, Ọlọ́run ti ṣe ìlérí fún òun nínú ìbúra pé nínú irú-ọmọ inú rẹ̀, òun yóò mú ọ̀kan jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀. 31Ní rí rí èyí tẹ́lẹ̀, ó sọ ti àjíǹde Kristi, pé a kò fi ọkàn rẹ̀ sílẹ̀ ni isà òkú, bẹ́ẹ̀ ni ara rẹ̀ kò rí ìdíbàjẹ́. 32Jesu náà yìí ni Ọlọ́run ti jí dìde sí ìyè, àwa pẹ̀lú sì jẹ́rìí sí èyí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.