Native Bible

Acts 2:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn ń ṣẹ̀fẹ̀, wọn sí wí pé, “Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí kún fún wáìnì tuntun”.

Acts 2:13 in English

Acts 2:13 · Berean Standard Bible

But others mocked them and said, “They are drunk on new wine!”

Context

11(àti àwọn Júù àti àwọn tí a ti ipa ẹ̀sìn sọ di Júù); àwọn ará Krete àti Arabia; àwa gbọ́ tí wọ́n sọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìyanu ńlá Ọlọ́run ni èdè wa.” 12Ẹnu sì ya gbogbo wọn, wọ́n sì wárìrì. Wọn wí fún ara wọn pé, “Kí ni èyí túmọ̀ sí?” 13Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn ń ṣẹ̀fẹ̀, wọn sí wí pé, “Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí kún fún wáìnì tuntun”. 14Nígbà náà ni Peteru dìde dúró pẹ̀lú àwọn mọ́kànlá yòókù, ó gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin Júù ènìyàn mi àti gbogbo ẹ̀yin tí ń gbé Jerusalẹmu, ẹ jẹ́ kí èyí kí ó yé yin; kí ẹ sì fetísí ọ̀rọ̀ mi. 15Àwọn wọ̀nyí kò mu ọtí yó, bí ẹ̀yin tí rò ó; wákàtí kẹta ọjọ́ sá à ni èyí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.