Ìṣe àwọn Aposteli 19:9
Acts 19:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkàn àwọn mìíràn nínú wọn di líle, tí wọn kò sì gbàgbọ́, tí wọn ń sọ̀rọ̀ ibi sí ọ̀nà náà níwájú ìjọ ènìyàn, ó lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sọ́tọ̀, ó sì ń sọ àsọyé lójoojúmọ́ ni ilé ìwé Tirannusi.
Acts 19:9 in English
Acts 19:9 · Berean Standard Bible
But when some of them stubbornly refused to believe and publicly maligned the Way, Paul took his disciples and left the synagogue to conduct daily discussions in the lecture hall of Tyrannus.
Context
7Iye àwọn ọkùnrin náà gbogbo tó méjìlá. 8Nígbà tí ó sì wọ inú Sinagọgu lọ ó fi ìgboyà sọ̀rọ̀ ni oṣù mẹ́ta, ó ń fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀, ó sì ń yí wọn lọ́kàn padà sí nǹkan tí i ṣe tí ìjọba Ọlọ́run. 9Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkàn àwọn mìíràn nínú wọn di líle, tí wọn kò sì gbàgbọ́, tí wọn ń sọ̀rọ̀ ibi sí ọ̀nà náà níwájú ìjọ ènìyàn, ó lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sọ́tọ̀, ó sì ń sọ àsọyé lójoojúmọ́ ni ilé ìwé Tirannusi. 10Èyí n lọ bẹ́ẹ̀ fún ìwọ̀n ọdún méjì; tó bẹ́ẹ̀ tí gbogbo àwọn tí ń gbé Asia gbọ́ ọ̀rọ̀ Jesu Olúwa, àti àwọn Júù àti àwọn Giriki. 11Ọlọ́run sì tí ọwọ́ Paulu ṣe àwọn àkànṣe iṣẹ́ ìyanu,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.