Native Bible

Acts 19:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èyí n lọ bẹ́ẹ̀ fún ìwọ̀n ọdún méjì; tó bẹ́ẹ̀ tí gbogbo àwọn tí ń gbé Asia gbọ́ ọ̀rọ̀ Jesu Olúwa, àti àwọn Júù àti àwọn Giriki.

Acts 19:10 in English

Acts 19:10 · Berean Standard Bible

This continued for two years, so that everyone who lived in the province of Asia,* Jews and Greeks alike, heard the word of the Lord.

Context

8Nígbà tí ó sì wọ inú Sinagọgu lọ ó fi ìgboyà sọ̀rọ̀ ni oṣù mẹ́ta, ó ń fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀, ó sì ń yí wọn lọ́kàn padà sí nǹkan tí i ṣe tí ìjọba Ọlọ́run. 9Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkàn àwọn mìíràn nínú wọn di líle, tí wọn kò sì gbàgbọ́, tí wọn ń sọ̀rọ̀ ibi sí ọ̀nà náà níwájú ìjọ ènìyàn, ó lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sọ́tọ̀, ó sì ń sọ àsọyé lójoojúmọ́ ni ilé ìwé Tirannusi. 10Èyí n lọ bẹ́ẹ̀ fún ìwọ̀n ọdún méjì; tó bẹ́ẹ̀ tí gbogbo àwọn tí ń gbé Asia gbọ́ ọ̀rọ̀ Jesu Olúwa, àti àwọn Júù àti àwọn Giriki. 11Ọlọ́run sì tí ọwọ́ Paulu ṣe àwọn àkànṣe iṣẹ́ ìyanu, 12tó bẹ́ẹ̀ tí a fi ń mú aṣọ àti aṣọ ìnuwọ́ rẹ̀ tọ àwọn ọlọkùnrùn lọ, ààrùn sì fi wọ́n sílẹ̀, àwọn ẹ̀mí búburú sì jáde kúrò lára wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.