Native Bible

Acts 18:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì lé wọn kúrò ní ibi ìtẹ́ ìdájọ́.

Acts 18:16 in English

Acts 18:16 · Berean Standard Bible

And he drove them away from the judgment seat.

Context

14Nígbà tí Paulu ń fẹ́ dáhùn, Gallioni wí fún àwọn Júù pé, “Ìbá ṣe pé ọ̀ràn búburú tàbí tí jàgídíjàgan kan ni, èmi ìbá gbè yín, ẹ̀yin Júù, 15Ṣùgbọ́n bí ó ti ṣe ọ̀ràn nípa ọ̀rọ̀ àti orúkọ, àti ti òfin yín ni, ki ẹ̀yin bojútó o fúnra yín; nítorí tí èmi kò fẹ́ ṣe onídàájọ́ nǹkan báwọ̀nyí.” 16Ó sì lé wọn kúrò ní ibi ìtẹ́ ìdájọ́. 17Gbogbo àwọn Giriki sì mú Sostene, olórí Sinagọgu, wọ́n sì lù ú níwájú ìtẹ́ ìdájọ́. Gallioni kò sì bìkítà fún nǹkan wọ̀nyí. 18Paulu sì dúró sí i níbẹ̀ lọ́jọ́ púpọ̀, nígbà tí ó sì dágbére fún àwọn arákùnrin, ó bá ọkọ̀ ojú omi lọ si Siria, àti Priskilla àti Akuila pẹ̀lú rẹ̀; ó tí fá orí rẹ̀ ni Kenkerea, nítorí tí ó ti jẹ́ ẹ̀jẹ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.