Ìṣe àwọn Aposteli 18:14
Acts 18:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí Paulu ń fẹ́ dáhùn, Gallioni wí fún àwọn Júù pé, “Ìbá ṣe pé ọ̀ràn búburú tàbí tí jàgídíjàgan kan ni, èmi ìbá gbè yín, ẹ̀yin Júù,
Acts 18:14 in English
Acts 18:14 · Berean Standard Bible
But just as Paul was about to speak, Gallio told the Jews, “If this matter involved a wrongdoing or vicious crime, O Jews, it would be reasonable for me to hear your complaint.
Context
12Nígbà tí Gallioni sì jẹ baálẹ̀ Akaia, àwọn Júù fi ìfìmọ̀ṣọ̀kan dìde sí Paulu wọn sì mú un wá síwájú ìtẹ́ ìdájọ́. 13Wọ́n wí pé, “Ọkùnrin yìí ń yí àwọn ènìyàn lọ́kàn padà, láti máa sin Ọlọ́run lòdì sí òfin.” 14Nígbà tí Paulu ń fẹ́ dáhùn, Gallioni wí fún àwọn Júù pé, “Ìbá ṣe pé ọ̀ràn búburú tàbí tí jàgídíjàgan kan ni, èmi ìbá gbè yín, ẹ̀yin Júù, 15Ṣùgbọ́n bí ó ti ṣe ọ̀ràn nípa ọ̀rọ̀ àti orúkọ, àti ti òfin yín ni, ki ẹ̀yin bojútó o fúnra yín; nítorí tí èmi kò fẹ́ ṣe onídàájọ́ nǹkan báwọ̀nyí.” 16Ó sì lé wọn kúrò ní ibi ìtẹ́ ìdájọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.