Ìṣe àwọn Aposteli 17:3
Acts 17:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó ń túmọ̀, ó sì ń fihàn pé, Kristi kò lè ṣàìmá jìyà, kí o sì jíǹde kúrò nínú òkú; àti pé, “Jesu yìí ẹni tí èmi ń wàásù fún yin, òun ni Kristi náà.”
Acts 17:3 in English
Acts 17:3 · Berean Standard Bible
explaining and proving that the Christ had to suffer and rise from the dead. “This Jesus I am proclaiming to you is the Christ,” he declared.
Context
1Nígbà tí wọn sì ti kọjá Amfipoli àti Apollonia, wọ́n wá sí Tẹsalonika, níbi tí Sinagọgu àwọn Júù wà. 2Àti Paulu, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, ó wọlé tọ̀ wọ́n lọ, ni ọjọ́ ìsinmi mẹ́ta ó sì ń bá wọn fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ nínú ìwé mímọ́. 3Ó ń túmọ̀, ó sì ń fihàn pé, Kristi kò lè ṣàìmá jìyà, kí o sì jíǹde kúrò nínú òkú; àti pé, “Jesu yìí ẹni tí èmi ń wàásù fún yin, òun ni Kristi náà.” 4A sì yí nínú wọn lọ́kàn padà, wọ́n sì darapọ̀ mọ́ Paulu àti Sila, bákan náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn olùfọkànsìn Helleni àti nínú àwọn obìnrin ọlọ́lá, kì í ṣe díẹ̀. 5Ṣùgbọ́n àwọn Júù jowú, wọn sì fa àwọn jàgídíjàgan nínú àwọn ọmọ ènìyàn mọ́ra, wọ́n ko ẹgbẹ́ jọ, wọ́n sì ń dá ìlú rú; wọ́n sì kọlu ilé Jasoni, wọ́n ń fẹ́ láti mú Paulu àti Sila jáde tọ àwọn ènìyàn lọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.