Native Bible

Acts 17:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àti Paulu, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, ó wọlé tọ̀ wọ́n lọ, ni ọjọ́ ìsinmi mẹ́ta ó sì ń bá wọn fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ nínú ìwé mímọ́.

Acts 17:2 in English

Acts 17:2 · Berean Standard Bible

As was his custom, Paul went into the synagogue, and on three Sabbaths he reasoned with them from the Scriptures,

Context

1Nígbà tí wọn sì ti kọjá Amfipoli àti Apollonia, wọ́n wá sí Tẹsalonika, níbi tí Sinagọgu àwọn Júù wà. 2Àti Paulu, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, ó wọlé tọ̀ wọ́n lọ, ni ọjọ́ ìsinmi mẹ́ta ó sì ń bá wọn fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ nínú ìwé mímọ́. 3Ó ń túmọ̀, ó sì ń fihàn pé, Kristi kò lè ṣàìmá jìyà, kí o sì jíǹde kúrò nínú òkú; àti pé, “Jesu yìí ẹni tí èmi ń wàásù fún yin, òun ni Kristi náà.” 4A sì yí nínú wọn lọ́kàn padà, wọ́n sì darapọ̀ mọ́ Paulu àti Sila, bákan náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn olùfọkànsìn Helleni àti nínú àwọn obìnrin ọlọ́lá, kì í ṣe díẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.