Ìṣe àwọn Aposteli 17:15
Acts 17:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn tí ó sin Paulu wá sì mú un lọ títí dé Ateni; nígbà tí wọ́n sì gba àṣẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ wá fún Sila àti Timotiu pé, ki wọn ó yára tọ òun wá, wọ́n lọ.
Acts 17:15 in English
Acts 17:15 · Berean Standard Bible
Those who escorted Paul brought him to Athens and then returned with instructions for Silas and Timothy to join him as soon as possible.
Context
13Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Júù tí Tẹsalonika mọ̀ pé, Paulu ń wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní Berea, wọ́n wá síbẹ̀ pẹ̀lú, wọ́n rú àwọn ènìyàn sókè. 14Nígbà náà ni àwọn arákùnrin rán Paulu jáde lọ́gán láti lọ títí de etí Òkun, ṣùgbọ́n Sila àti Timotiu dúró ní Berea. 15Àwọn tí ó sin Paulu wá sì mú un lọ títí dé Ateni; nígbà tí wọ́n sì gba àṣẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ wá fún Sila àti Timotiu pé, ki wọn ó yára tọ òun wá, wọ́n lọ. 16Nígbà tí Paulu dúró dè wọ́n ni Ateni, ẹ̀mí rẹ̀ ru nínú rẹ̀, nígbà tí ó rí pé ìlú náà kún fún òrìṣà. 17Nítorí náà ó ń bá àwọn Júù fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ nínú Sinagọgu, àti àwọn olùfọkànsìn, àti àwọn tí ó ń bá pàdé lọ́jà lójoojúmọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.