Native Bible

Acts 16:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lọ́jọ́ ìsinmi, àwa sí jáde lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú náà, lẹ́bàá odò kan, níbi tí a rò pé ibi àdúrà wà; àwa sí jókòó, a sì bá àwọn obìnrin tí o péjọ sọ̀rọ̀.

Acts 16:13 in English

Acts 16:13 · Berean Standard Bible

On the Sabbath we went outside the city gate along the river, where it was customary to find a place of prayer. After sitting down, we spoke to the women who had gathered there.

Context

11Nítorí náà nígbà tí àwa ṣíkọ̀ ní Troasi a ba ọ̀nà tààrà lọ sí Samotrakea, ni ọjọ́ kejì a sì dé Neapoli; 12láti ibẹ̀ àwa sì lọ si Filipi, tí í ṣe ìlú Makedonia, olú ìlú ìhà ibẹ̀, ìlú lábẹ́ Romu, àwa sì jókòó ní ìlú yìí fún ọjọ́ mélòó kan. 13Lọ́jọ́ ìsinmi, àwa sí jáde lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú náà, lẹ́bàá odò kan, níbi tí a rò pé ibi àdúrà wà; àwa sí jókòó, a sì bá àwọn obìnrin tí o péjọ sọ̀rọ̀. 14Àti obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Lidia, elése àlùkò, ará ìlú Tiatira, ẹni tí ó sin Ọlọ́run, ó gbọ́ ọ̀rọ̀ wa, ọkàn ẹni tí Olúwa ṣí láti fetísí ohun tí a tí ẹnu Paulu sọ. 15Nígbà tí a sí bamitiisi rẹ̀, àti àwọn ara ilé rẹ̀, ó bẹ̀ wá, wí pé, “Bí ẹ̀yin bá kà mí ni olóòtítọ́ sí Olúwa, ẹ wá si ilé mi, kí ẹ sí wọ̀ níbẹ̀!” O sí rọ̀ wá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.