Native Bible

Acts 16:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà nígbà tí àwa ṣíkọ̀ ní Troasi a ba ọ̀nà tààrà lọ sí Samotrakea, ni ọjọ́ kejì a sì dé Neapoli;

Acts 16:11 in English

Acts 16:11 · Berean Standard Bible

We sailed from Troas straight to Samothrace, and the following day on to Neapolis.

Context

9Ìran kan si hàn sì Paulu ni òru, ọkùnrin kan ará Makedonia dúró, ó sì ń bẹ̀ ẹ́, wí pé, “Rékọjá wá sí Makedonia, kí o sí ràn wá lọ́wọ́!” 10Nígbà tí ó sì tí rí ìran náà, lọ́gán ó múra láti lọ sí Makedonia, a ka á sí pé, Ọlọ́run tí pè wá láti wàásù ìyìnrere fún wọn. 11Nítorí náà nígbà tí àwa ṣíkọ̀ ní Troasi a ba ọ̀nà tààrà lọ sí Samotrakea, ni ọjọ́ kejì a sì dé Neapoli; 12láti ibẹ̀ àwa sì lọ si Filipi, tí í ṣe ìlú Makedonia, olú ìlú ìhà ibẹ̀, ìlú lábẹ́ Romu, àwa sì jókòó ní ìlú yìí fún ọjọ́ mélòó kan. 13Lọ́jọ́ ìsinmi, àwa sí jáde lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú náà, lẹ́bàá odò kan, níbi tí a rò pé ibi àdúrà wà; àwa sí jókòó, a sì bá àwọn obìnrin tí o péjọ sọ̀rọ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.