Native Bible

Acts 15:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó yẹ lójú àwa, bí wa ti fi ìmọ̀ ṣọ̀kan láti yan ènìyàn láti rán wọn sí yín, pẹ̀lú Barnaba àti Paulu àwọn olùfẹ́ wa.

Acts 15:25 in English

Acts 15:25 · Berean Standard Bible

So we all agreed to choose men to send to you along with our beloved Barnabas and Paul,

Context

23Wọn sì kọ ìwé lé wọn lọ́wọ́ báyìí pé, Àwọn aposteli, àti àwọn alàgbà, tí ó jẹ́ ti aláìkọlà tí ó wà ní Antioku, àti ní Siria, àti ní Kilikia. 24Níwọ́n bí àwa ti gbọ́ pé, àwọn kan ti ó ti ọ̀dọ̀ wa jáde wá ń fi ọ̀rọ̀ yọ yín lẹ́nu, tí wọ́n ń yí yín ní ọkàn padà (wí pé, ẹ kò gbọdọ̀ ṣàìmá kọ ilà, àti ṣàìmá pa òfin Mose mọ́), ẹni tí àwa kò fún ní àṣẹ. 25Ó yẹ lójú àwa, bí wa ti fi ìmọ̀ ṣọ̀kan láti yan ènìyàn láti rán wọn sí yín, pẹ̀lú Barnaba àti Paulu àwọn olùfẹ́ wa. 26Àwọn ọkùnrin ti ó fi ọkàn wọn wéwu nítorí orúkọ Olúwa wa Jesu Kristi. 27Nítorí náà àwa rán Judasi àti Sila àwọn tí yóò sì fi ọ̀rọ̀ ẹnu sọ ohun kan náà fún yín.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.