Native Bible

Acts 15:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Níwọ́n bí àwa ti gbọ́ pé, àwọn kan ti ó ti ọ̀dọ̀ wa jáde wá ń fi ọ̀rọ̀ yọ yín lẹ́nu, tí wọ́n ń yí yín ní ọkàn padà (wí pé, ẹ kò gbọdọ̀ ṣàìmá kọ ilà, àti ṣàìmá pa òfin Mose mọ́), ẹni tí àwa kò fún ní àṣẹ.

Acts 15:24 in English

Acts 15:24 · Berean Standard Bible

It has come to our attention that some went out from us without our authorization and unsettled you, troubling your minds by what they said.*

Context

22Nígbà nà án ni ó tọ́ lójú àwọn aposteli, àti àwọn alàgbà pẹ̀lú gbogbo ìjọ, láti yan ènìyàn nínú wọn, àti láti rán wọ́n lọ sí Antioku pẹ̀lú Paulu àti Barnaba: Judasi ti a ń pè àpèlé rẹ̀ ní Barsaba, àti Sila, ẹni tí ó lórúkọ nínú àwọn arákùnrin. 23Wọn sì kọ ìwé lé wọn lọ́wọ́ báyìí pé, Àwọn aposteli, àti àwọn alàgbà, tí ó jẹ́ ti aláìkọlà tí ó wà ní Antioku, àti ní Siria, àti ní Kilikia. 24Níwọ́n bí àwa ti gbọ́ pé, àwọn kan ti ó ti ọ̀dọ̀ wa jáde wá ń fi ọ̀rọ̀ yọ yín lẹ́nu, tí wọ́n ń yí yín ní ọkàn padà (wí pé, ẹ kò gbọdọ̀ ṣàìmá kọ ilà, àti ṣàìmá pa òfin Mose mọ́), ẹni tí àwa kò fún ní àṣẹ. 25Ó yẹ lójú àwa, bí wa ti fi ìmọ̀ ṣọ̀kan láti yan ènìyàn láti rán wọn sí yín, pẹ̀lú Barnaba àti Paulu àwọn olùfẹ́ wa. 26Àwọn ọkùnrin ti ó fi ọkàn wọn wéwu nítorí orúkọ Olúwa wa Jesu Kristi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.