Ìṣe àwọn Aposteli 14:2
Acts 14:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n àwọn aláìgbàgbọ́ Júù rú ọkàn àwọn aláìkọlà sókè, wọ́n sì mú wọn ni ọkàn ìkorò sí àwọn arákùnrin náà.
Acts 14:2 in English
Acts 14:2 · Berean Standard Bible
But the unbelieving Jews stirred up the Gentiles and poisoned their minds against the brothers.
Context
1Ó sí ṣe, ni Ikoniomu, Paulu àti Barnaba jùmọ̀ wọ inú Sinagọgu àwọn Júù lọ, wọ́n sì sọ̀rọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Júù àti àwọn Helleni gbàgbọ́. 2Ṣùgbọ́n àwọn aláìgbàgbọ́ Júù rú ọkàn àwọn aláìkọlà sókè, wọ́n sì mú wọn ni ọkàn ìkorò sí àwọn arákùnrin náà. 3Nítorí náà Paulu àti Barnaba gbé ibẹ̀ pẹ́, wọ́n ń fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nínú Olúwa, ẹni tí ó jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, ó sì mu kí iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu máa ti ọwọ́ wọn ṣe. 4Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ìlú náà pín sí méjì: apá kan dàpọ̀ mọ́ àwọn Júù, apá kan pẹ̀lú àwọn aposteli.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.