Native Bible

Acts 13:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n Elimu oṣó (nítorí bẹ́ẹ̀ ni ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀) takò wọ́n, ó ń fẹ́ pa baálẹ̀ ni ọkàn dà kúrò ni ìgbàgbọ́.

Acts 13:8 in English

Acts 13:8 · Berean Standard Bible

But Elymas the sorcerer (for that is what his name means) opposed them and tried to turn the proconsul from the faith.

Context

6Nígbà tí wọ́n sì la gbogbo erékùṣù já dé Pafosi, wọ́n rí ọkùnrin oṣó àti wòlíì èké kan ti i ṣe Júù, orúkọ ẹni ti ó ń jẹ́ Bar-Jesu. 7Ó wà lọ́dọ̀ Segiu Paulusi baálẹ̀ ìlú náà tí í ṣe amòye ènìyàn. Òun náà ni ó ránṣẹ́ pe Barnaba àti Saulu, nítorí tí ó fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. 8Ṣùgbọ́n Elimu oṣó (nítorí bẹ́ẹ̀ ni ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀) takò wọ́n, ó ń fẹ́ pa baálẹ̀ ni ọkàn dà kúrò ni ìgbàgbọ́. 9Ṣùgbọ́n Saulu ti a ń pè ni Paulu, ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì tẹjúmọ́ Elimu, ó sì wí pé, 10“Ìwọ ti ó kún fún àrékérekè gbogbo, àti fún ìwà ìkà gbogbo, ìwọ ọmọ èṣù, ìwọ ọ̀tá ohun gbogbo, ìwọ kì yóò ha dẹ́kun láti máa yí ọ̀nà òtítọ́ Olúwa po?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.