Ìṣe àwọn Aposteli 13:29
Acts 13:29 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí wọ́n ti mú nǹkan gbogbo ṣẹ ti a kọ̀wé nítorí rẹ̀, wọn sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ kúrò lórí igi, wọ́n sì tẹ́ ẹ sí ibojì.
Acts 13:29 in English
Acts 13:29 · Berean Standard Bible
When they had carried out all that was written about Him, they took Him down from the tree and laid Him in a tomb.
Context
27Nítorí àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu, àti àwọn olórí wọn, nítorí tiwọn kò mọ̀ Jesu, tí wọn kò sì ní òye ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì, tí a ń kà ní ọjọọjọ́ ìsinmi fún wọn, kò yé wọn, wọ́n mú ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì yìí ṣẹ nípa dídá a lẹ́bi. 28Àti bí wọn kò tilẹ̀ ti rí ọ̀ràn ikú sí i, síbẹ̀ wọn rọ Pilatu láti pa á. 29Bí wọ́n ti mú nǹkan gbogbo ṣẹ ti a kọ̀wé nítorí rẹ̀, wọn sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ kúrò lórí igi, wọ́n sì tẹ́ ẹ sí ibojì. 30Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òkú, 31o sì farahàn lọ́jọ́ púpọ̀ fún àwọn tí ó bá a gòkè láti Galili wá sí Jerusalẹmu, àwọn tí í ṣe ẹlẹ́rìí rẹ̀ nísinsin yìí fún àwọn ènìyàn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.