Native Bible

Acts 13:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ǹjẹ́ nísinsin yìí wò ó, ọwọ́ Olúwa ń bẹ lára rẹ̀, ìwọ ó sì fọjú ìwọ kì yóò rí oòrùn ní sá à kan!” Lójúkan náà, ìkùùkuu àti òkùnkùn sí bò ó; ó sì ń wá ènìyàn kiri láti fa òun lọ́wọ́ lọ.

Acts 13:11 in English

Acts 13:11 · Berean Standard Bible

Now look, the hand of the Lord is against you, and for a time you will be blind and unable to see the light of the sun.” Immediately mist and darkness came over him, and he groped about, seeking someone to lead him by the hand.

Context

9Ṣùgbọ́n Saulu ti a ń pè ni Paulu, ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì tẹjúmọ́ Elimu, ó sì wí pé, 10“Ìwọ ti ó kún fún àrékérekè gbogbo, àti fún ìwà ìkà gbogbo, ìwọ ọmọ èṣù, ìwọ ọ̀tá ohun gbogbo, ìwọ kì yóò ha dẹ́kun láti máa yí ọ̀nà òtítọ́ Olúwa po? 11Ǹjẹ́ nísinsin yìí wò ó, ọwọ́ Olúwa ń bẹ lára rẹ̀, ìwọ ó sì fọjú ìwọ kì yóò rí oòrùn ní sá à kan!” Lójúkan náà, ìkùùkuu àti òkùnkùn sí bò ó; ó sì ń wá ènìyàn kiri láti fa òun lọ́wọ́ lọ. 12Nígbà tí baálẹ̀ rí ohun tí ó ṣe, ó gbàgbọ́, ẹnu sì yà á sì ẹ̀kọ́ Olúwa. 13Nígbà tí Paulu àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ si ṣíkọ̀ ni Pafosi wọ́n wá sí Perga ni Pamfilia: Johanu sì fi wọ́n sílẹ̀, ó sì padà lọ sí Jerusalẹmu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.