Ìṣe àwọn Aposteli 12:3
Acts 12:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí ó sì rí pé èyí dùn mọ́ àwọn Júù nínú, ó sì nawọ́ mú Peteru pẹ̀lú. Ó sì jẹ́ ìgbà àjọ àìwúkàrà.
Acts 12:3 in English
Acts 12:3 · Berean Standard Bible
And seeing that this pleased the Jews, Herod proceeded to seize Peter during the Feast of Unleavened Bread.*
Context
1Ní àkókò ìgbà náà ni Herodu ọba sì nawọ́ rẹ̀ mú àwọn kan nínú ìjọ, pẹ̀lú èrò láti pọ́n wọn lójú. 2Ó sì fi idà pa Jakọbu arákùnrin Johanu. 3Nígbà tí ó sì rí pé èyí dùn mọ́ àwọn Júù nínú, ó sì nawọ́ mú Peteru pẹ̀lú. Ó sì jẹ́ ìgbà àjọ àìwúkàrà. 4Nígbà tí o sì mú un, ó fi i sínú túbú, ó fi lé àwọn ẹ̀ṣọ́ mẹ́rin ti ọmọ-ogun lọ́wọ́ láti máa ṣọ́ ọ. Herodu ń rò láti mú un jáde fún àwọn ènìyàn lẹ́yìn ìrékọjá fún ìdájọ́. 5Nítorí náà wọn fi Peteru pamọ́ sínú túbú; ṣùgbọ́n ìjọ ń fi ìtara gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run fún un.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.