Ìṣe àwọn Aposteli 11:12
Acts 11:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ̀mí sì wí fún mi pé, kí èmi bá wọn lọ, ki èmi má ṣe kọminú ohunkóhun. Àwọn arákùnrin mẹ́fà wọ̀nyí sì bá mi lọ, a sì wọ ilé ọkùnrin náà.
Acts 11:12 in English
Acts 11:12 · Berean Standard Bible
The Spirit told me to accompany them without hesitation. These six brothers also went with me, and we entered the man’s home.
Context
10Èyí sì ṣẹlẹ̀ nígbà mẹ́ta; a sì tún fa gbogbo rẹ̀ sókè ọ̀run. 11“Sì wò ó, lójúkan náà ọkùnrin mẹ́ta dúró níwájú ilé ti a gbé wà, ti a rán láti Kesarea sí mi. 12Ẹ̀mí sì wí fún mi pé, kí èmi bá wọn lọ, ki èmi má ṣe kọminú ohunkóhun. Àwọn arákùnrin mẹ́fà wọ̀nyí sì bá mi lọ, a sì wọ ilé ọkùnrin náà. 13Ó sì sọ fún wa bí òun ti rí angẹli kan tí ó dúró ní ilé rẹ̀, tí ó sì wí pé, ‘Ránṣẹ́ lọ sí Joppa, kí ó sì pe Simoni tí àpèlé rẹ̀ jẹ́ Peteru; 14ẹni tí yóò sọ ọ̀rọ̀ fún ọ, nípa èyí tí a ó fi gba ìwọ àti gbogbo ilé rẹ là.’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.